~Translation ~
Òyèkú bìwòrì
Gbóró gbóró gìdì
Ajan gbóró gìdì
Cast ifá for lájosìn
The one that worship oya with blessings
The one that is destined to worship oya to be successful
People going to ipo, People going to offa
Whenever someone is born with this odù ifá
Must worship òrìsà oya and take her as his or her priority
For him or her to be successful in life.
Àse òrìsà?
]]>Sunday Shodipe tí wà láhàámọ wa– Alukoro ọlọ́pàá Ọ̀yọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti sọ ọ̀rọ̀ kanranjágbọ́n afurasí Sunday Shodipe di ẹgbẹ̀rún ìsáǹsá tí wọn ò lè sá mọ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, bí ìròyìn tó ń tẹ̀wà lọ́wọ́ ṣe sọ ọ́ di mímọ̀ pé ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti tẹ arákùnrin kan, Sunday Shodipe tó sá mọ́ wọn lọ́wọ́ láìpẹ́ yìí.
Shodipe jẹ́ afurasí tí wọ́n ti kọ mú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣekúpani tó ń wáyé láìpẹ́ yìí lágbègbè Akínyẹlé ní ìlú Ìbàdàn.
Kò tíì dájú ibi tí wọ́n ti rí i mú, ṣùgbọ́n alukoro ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Fádèyí Olugbenga ṣọ̀rọ̀, ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó tí wà lákàtà ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá.
Bí ẹ kò bá gbàgbé, ìròyìn jáde rẹpẹtẹ nígbà tí ọwọ́ kọ́ tẹ Shodipe tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún Kódà, àti ìgbà tó tún sá lọ mọ́ ọlọ́pàá lọ́wọ́, ìròyìn kò tíì tán nílẹ̀ títí di àkókò yìí.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́, ó ti pẹ́ díẹ̀ tí Ìròyìn sọ pé afurasí ọ̀daràn yìí ló wà nídìí ikú ọ̀wọọwọ̀ọ́ tó ń wáyé lágbègbè Ìjọba ìbílẹ̀ Akínyẹlé nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́.
]]>Ayé ń lọ sópin, ohun tétí ò fẹ́ ẹ̀ gbọ́ rí lojú ń rí báyìí o.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu lóri ọkùnrin kan tí orukọ́ rẹ̀ ń jẹ́ Emmanuel Egbu tí wọ́n ní ó ń fi ìgbẹ́ jẹ búrẹ́dì ní orí àkìntàn nílùú Ìbàdàn.
Wọ́n ní àwọn kan ní àdúgbò Sáńgo ló ké gbàjarè tí wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ náà tó ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá àgbègbè náà léti ki àwọn ará àdúgbò tó ṣe ìdájọ́ fún un láti ọwọ́ ara wọ́n.
Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá nípìnlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olugbenga Fadeyi ṣàlàye fún akọròyìn pé, ní kété tí wọ́n mú ọkùnrin náà ni wọ́n ti gba ọ̀rọ̀ sílẹ̀ lẹ́nu rẹ̀ ti wọ́n sì gba onírúurú ìgbẹ́ ti wọ́n ri lọ́wọ́ rẹ̀ láti gbé e lọ fún àyẹ̀wò.
Yàtọ̀ sí ìròyìn kan tó sọ pé gbajúgbajà olùtajà àwọn èròjà àṣara àti irun lóge ni ọkùnrin náà tó sì ni ṣọ́ọ̀bù ńlá ńlá ni àdúgbò Sáńgo nílùú Ìbàdàn àti pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ra ilé ńlá kan ni, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ọjọ́ Sátidé, ọjọ́ kejìlélógún ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, àjọ ọlọ́pàá sì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà ni.
Fadeyi ní òun kò le fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ àfi tí ìwádìí bá parí ṣùgbọ́n ní òótọ́ ni àwọn bá ìgbẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, tí àwọn sì ti kó wọ́n lọ fún àwọn àyẹwò tó yẹ.
Ẹ̀wẹ̀, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ọkùnrin náà wà ní àgọ́ ọlọ́pàá agbègbè Sáńgo nílùú Ìbàdàn.
Fẹ́mi Akínṣọlá
]]>Ajakale arun coronavirus ti n pa eni kukuru, to n pa eni giga, ti ko mo olowo yato fun talaka, ko mo oba bee ni ko mo ijoye, ko ki n ja ija elesinmesin, ko si ohun to kan an pelu eleyameya.
Ajakale ohun naa lo ko lu odidi bii gomina mejo ni orileede yi, ni eyi ti Arakunrin Rotimi Akeredolu wa ninu won. Ose to koja lo kede funra re pe ayewo oun gbe arun coronavirus jade. Gomina yii ba lo fun iwosan, o bere si ni sise ofiisi nile.
Gomina yii naa lo tun kede ni irole oni pe ki a ba oun dupe nipa esi ayewo to tun jade lonii ti o si gbee pe aisan naa ti kuro ni ago ara Gomina Akeredolu.
Yínká Àlàbí
]]>Ṣé wọ́n ní kìí jẹ́ ti baba t’ọmọ, kó mọ́ ní ààlà. Èyí ló díá fún bí àwọn ẹbí olóògbé Abíọ́lá Ajímọ̀bi tí sàlàyé pé ,kí àwọn olùkẹ́dùn, ó má wulẹ̀ dààmu yọjú sí bi fìdáù, ní ìbámu pẹ̀lú n tí àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì n sọ , bí ó ti jẹ́ pé òní, ọjọ́ karùn-ún, oṣù Keje, ni àdúrà ọjọ́ kẹjọ yóó wáyé fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀rí tó di olóògbé, Sẹ́nétọ̀ Isiaka Abíọ́lá Ajímọ̀bi.
Ètò àdúrà náà, Fìdáù, wà ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àti ìṣẹ ẹ̀sìn Islam. Ìdílé olóògbé sọ nínú Ìkéde tó fi síta fún ètò àdúrà náà pé, ẹbí Ajímọ̀bi nìkan ni ètò àdúrà náà wà fún, nítorí òfin tó rọ̀ mọ́ ìtànkálẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì.
Ṣùgbọ́n ṣá, wọ́n ní àwọn aráàlú yóó ní àǹfààní láti wo bí ètò àdúrà náà bá ṣe ń lọ lórí amóhùnmáwòrán àti lórí ẹ̀rọ ayélujára.
Ọjọ́ kẹẹdọgbọn, oṣù Kẹfà, ọdún 2020, ni Abíọ́lá Ajímọ̀bi kú, síléèwòsàn First Cardiologist, tó wà nílùú Èkó, lẹ́yìn tó ní àrùn Kofi-19.
Ẹni àádọ́rin ọdún olóògbé Abíọ́lá Ajímọ̀bi ko tó tẹ́rí gbaṣọ.
Fẹ́mi Akínṣọlá
]]>Àkànjí ẹ̀rù Sheeeeuuu,ibi o fàdàgbá ayé rọ̀ sí, ọmọ ni yóó lòyókú.
]]>Ṣé ọlọ́tọ̀ ní t’óun ọ̀tọ̀, a díá fún òkú tó kú ńlé, tí wọ́n sin s’óko.
Àgbà Imọlẹ̀ kan nlẹ yìí ti fèsì sí ìṣẹ̀lẹ̀ ààrá tó sán láìpẹ́ yìí pa àwọn òṣìṣẹ́ Àjọ ẹṣọ ojú u pópó mẹta ,o ní,ìkìlọ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ àrá tó sán pa àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ojú-pópó (Federal Road Safety Corps) mẹ́ta, tí òp̣ò ̣sì farapa nípìnlẹ̀ Ògùn.
Ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀, Ògbó Awo Yẹmí Ẹlẹ́buùbọn tí tún se Àràbà Òṣogbo tẹnumọ́ ọ bẹ́ẹ̀ nígbà tó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ajániláyà pàtì ọ̀hún.
Itele-Ijebu ní Old-gate ni ìsẹ̀lẹ̀ náàt ti ṣẹlẹ̀ ní Ọjọ́rú.
A gbọ́ pé bí àrá yìí ṣe sán ló pa àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́ta náà lójú ẹsẹ̀, tó sì jan àwọn míì mọ́lẹ̀, ti gbogbo agbègbè náà sì di ibùdó erujeje lójú ẹsẹ̀.
Ìròyìn tó tẹ̀wà lọ́wọ́ tún sọ pé àwọn oníṣàngó lọ ṣètùtù tó yẹ, kò tó di pé wọ́n gbé òkú wọn fún ìjọba.
Àmọ́, Àgbà Imọlẹ̀ náà ní ìṣẹ́ kan kìí ṣẹ́ lásán, tí kò bá sì nídìí, obìnrin kìí jẹ́ ikúmólú.
Bàbá Ṣàngó kìí sàdédé pààyàn bẹ́ẹ̀ tí kò bá jẹ́ wípé àwọn èèyàn náà ti ṣe nǹkan àìtọ́ kan.
Bàbá Ẹlẹ́buùbọn ní ó yẹ kí wọ́n ṣe ṣètùtù láti dènà àjálù mìíràn papàá jùlọ àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ àwọn èèyàn tó kú.
]]>